ResearchApp

...where knowledge is applied.

Àlọ́ (1): Sọ́gbá ẹ

By Iyùn Adé

Àti kékeré ni mo ti gbọ́n ọgbọ́n pé ìwọ̀nba là á dá sí ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀, pàápàá tó bá ti jọ mọ tìjá.

Ilé elérò ni a gbé dàgbà l’Èkó kó tó di wípé a kó padà s’ábúlé. Iya kan wa tó ń gbé nínú ọgbà wa nígbànáà. Ìyá ìbejì ni gbogbo wá mọ̀ ọ́ sí, àmọ́ (sugbon) ẹlẹ́dẹ̀ ń yájú lẹ́gbẹ́ màmá yìí ni, nipa ka bí ọmọ jọ. Ọmọ mẹ́tàlá ni ìyá ìbejì bí, bàbá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni gbogbo wọ́n ni. Bẹ́ẹ̀ bá dá ọ̀rọ̀ Ìjẹ̀bú sílẹ̀, párá ló ma ni, “A! Mo bímọ fun wọn nbẹun”. Bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ Ìjẹ̀sà, “Ilu bàbá Ọmọladun (ọmọ rẹ kẹ́ta) niyun”.

Gbéborùn tó tó Iya ìbejì ò sí. Bó bá kúrò níyàràa Lágbájá, tó lóun lọ bá wọn ṣeré, yóò ya ọ̀dọ̀ Tàmẹ̀dù láti lọ ro ẹjọ́ Lágbájá. Bẹ́ẹ̀ bá ń wá “má fi lọ̀ mí n dási, iya ìbejì ló ń jẹ bẹ́ẹ̀.

Ṣé ẹ sì mọ wípé nílé elérò, ìjà ò lè ṣaláì má ṣẹlẹ̀. Bíjà bá bẹ́ ẹ́ lẹ̀, iya Ìbejì á á ti fò dìrò sí àárín ìjà. “Ẹ dákun, ẹ mọ́ jà mọ, kọ dáa”. Bó tilẹ̀ jẹ́ wípé nígbà míràn, àbòsí rẹ̀ ló máa fa èdè àìyedè láàrin àwọn oníjà méjèèjì.

Ó ti ń ṣe é tó ń mu jẹ, àmọ́ ọjọ́ tó máa yíwọ́ mọ lọ́wọ́, ariwo la gbọ́ lẹ́hínkùlé, ti gbogbo wá tú bọ́ta. Ayálégbé tuntun, Iya Féètì, lo wọ̀yáàjà pẹ̀lú Ìyá Àbáyọ̀́. Wọ́n ti fẹ́rẹ̀ tú ara wọn sí ìhòhò tań. Ẹní bá rí bi Iya Féètì ṣe rí núẹńuẹ́ á á ní kò le è dákọ kan jẹ tan. Àmọ́, Iya Féètì tí mo rí níta yìí, níṣe ní egungun rẹ̀ ń ràn bí ẹni àlùjọ̀ọ̀nú gbé wọ̀. Ó yí Ìyá Àbáyọ̀́ ẹlẹ́nu rẹ́sọ̀ mọ́lè, tó ń kù ú ní ẹ̀ṣẹ́ lọ́tún losì.

Ṣèbí ẹni tó bá gbọ́n, á ti mọ̀ wípé nirú ìjà báyìí, làti ọ̀ọ́kan lèyan ti máa ń rawọ ẹ̀bẹ̀ si àwọn to n ja. Àmọ́, rárá o; olùlàjà ti fò fẹ̀rẹ̀ bọ́ síwájú. Kí ló ní kí òun fa Iya Féètì kúrò ni orí Iya Àbáyọ̀́ báyìí, àfi làì!!!! Ìfọ́tí ló dún létí Ìyá Ìbejì. Ìgúnpá tí Iya Féètì tún máa gbé sókè báyìí, àgbọ̀n Ìyá Ìbejì ló bá pade. Ni Ìyá Ìbejì figbe ta, “Yéè!!! Ẹ gbà mí, mọ kú o!” Ariwo Ìyá Ìbejì kò mà dí àwọn oníjà lọ́wọ́ o, níṣe ni Ìyá Féètì kọjú mọ́ nínà tó ń na Ìyá Àbáyọ̀́ lọ.

Láti ọjọ́ yẹn títí ta fi kó kúrò nílé náà, bíjà bá bẹ̀rẹ̀ báyìí, ńṣe ni Ìyá Ìbejì máa pa lọ́lọ́ sínú ìyẹ̀wù rẹ̀. Ẹni ẹlẹ́ni, ta ló tún fẹ jẹ Ìfọ́tí Ẹlẹ́ẹ̀kejì?

Comments

comments

Updated: January 24, 2018 — 8:05 pm
Copyright HefTee Media and Event Consult 2015 Frontier Theme